Sáàmù 99:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Olúwa tóbi ní Síónì;o sì ga jù gbogbo orílẹ̀ èdè lọ.

3. Kí wọ́n sì yín orúkọ Rẹ̀ tí ó tóbití ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.

4. Olúwa tóbi lọba, ó fẹ́ òdodo ó dá ìdọ́gba sílẹ̀;ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí o yẹ nínú Jákọ́bù.

5. Gbígbé ga ní Olúwa Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

6. Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀wọ́n képe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

7. Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,wọ́n pa ẹrí Rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

Sáàmù 99