11. Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ.
12. Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi?
13. Oluwa si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itùnu da angeli ti mba mi sọ̀rọ lohùn.