19. Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn.
20. Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.