15. Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú?
16. Njẹ bi akọso ba mọ́, bẹ̃li akopọ: bi gbòngbo ba si mọ́, bẹ si li awọn ẹ̀ka rẹ̀ na.
17. Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na;
18. Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ.
19. Njẹ iwọ o wipe, A ti fà awọn ẹ̀ka na ya, nitori ki a le lọ́ mi sinu rẹ̀.
20. O dara; nitori aigbagbọ́ li a ṣe fà wọn ya kuro, iwọ si duro nipa igbagbọ́ rẹ. Máṣe gbé ara rẹ ga, ṣugbọn bẹ̀ru:
21. Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si.