20. Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn.
21. Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.
22. Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn.
23. OLUWA si sọ fun Mose pe,
24. Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ.