9. Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn.
10. Ibinu Ọlọrun si rú si wọn nigbana, o si bura, wipe,
11. Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata.
12. Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne ọmọ Kenissi, ati Joṣua ọmọ Nuni: nitoripe awọn li o tẹle OLUWA lẹhin patapata.
13. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si mu wọn rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, titi gbogbo iran na, ti o ṣe buburu li oju OLUWA fi run.
14. Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli.
15. Nitoripe bi ẹnyin ba yipada kuro lẹhin rẹ̀, on o si tun fi wọn silẹ li aginjù; ẹnyin o si run gbogbo awọn enia yi.
16. Nwọn si sunmọ ọ wipe, Awa o kọ́ ile-ẹran nihinyi fun ohunọ̀sin wa, ati ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ wa: