52. Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli.
53. (Nitoripe awọn ologun ti kó ẹrù, olukuluku fun ara rẹ̀.)
54. Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lọwọ awọn balogun ọrọrún nwọn si mú u wá sinu agọ́ ajọ, ni iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA.