Num 24:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.

9. O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú.

10. Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi.

11. Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá.

12. Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe,

Num 24