Num 11:32-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Awọn enia si duro ni gbogbo ọjọ́ na, ati ni gbogbo oru na, ati ni gbogbo ọjọ́ keji, nwọn si nkó aparò: ẹniti o kó kére, kó òṣuwọn homeri mẹwa: nwọn si sá wọn silẹ fun ara wọn yi ibudó ká.

33. Nigbati ẹran na si mbẹ lãrin ehín wọn, ki nwọn ki o tó jẹ ẹ, ibinu OLUWA si rú si awọn enia na, OLUWA si fi àrun nla gidigidi kọlù awọn enia na.

34. A si pè orukọ ibẹ̀ na ni Kibrotu-hattaafa: nitoripe nibẹ̀ ni nwọn gbé sinku awọn enia ti o ṣe ifẹkufẹ.

35. Awọn enia na si dide ìrin wọn lati Kibrotu-hattaafa lọ si Haserotu; nwọn si dó si Haserotu.

Num 11