17. Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà.
18. Esra si kà ninu iwe ofin Ọlọrun li ojojumọ, lati ọjọ kini titi de ọjọ ikẹhin. Nwọn si pa àse na mọ li ọjọ meje, ati lọjọ kẹjọ, nwọn ni apejọ ti o ni ìronu gẹgẹ bi iṣe wọn.