Neh 4:12-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá.

13. Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn.

14. Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin.

Neh 4