12. Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
13. Ọ̀rọ nyin ti jẹ lile si mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ọ̀rọ kili awa sọ si ọ?
14. Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?
15. Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si.