Mak 7:25-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀:

26. Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀.

27. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá.

28. O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili.

29. O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ.

30. Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete.

31. O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli.

32. Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e.

Mak 7