Mak 10:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.

2. Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ?

Mak 10