11. Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:
12. Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA:
13. Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni:
14. Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀:
15. Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀:
16. Ki alufa ki o si tẹ̀ ika rẹ̀ ọtún bọ̀ inu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀, ki o si fi ika rẹ̀ ta ninu oróro na nigba meje niwaju OLUWA:
17. Ati ninu oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ ni ki alufa ki o fi si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, lori ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: