3. Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, awa si ngbadura fun nyin nigbagbogbo,
4. Nigbati awa gburó igbagbọ́ nyin ninu Kristi Jesu, ati ifẹ ti ẹnyin ni si gbogbo awọn enia mimọ́,
5. Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere,
6. Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ:
7. Ani bi ẹnyin ti kọ́ lọdọ Epafra iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa olufẹ, ẹniti iṣe olõtọ iranṣẹ Kristi nipo wa,
8. Ti o si ròhin ifẹ nyin ninu Ẹmí fun wa pẹlu.