40. Bẹni nwọn gbé okú Jesu, nwọn si fi aṣọ ọ̀gbọ dì i pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju ti ri ni isinkú wọn.
41. Agbala kan si wà nibiti a gbé kàn a mọ agbelebu; ibojì titun kan sí wà ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti itẹ́ ẹnikẹni si ri.
42. Njẹ nibẹ ni nwọn si tẹ́ Jesu si, nitori Ipalẹmọ́ awọn Ju; nitori ibojì na wà nitosi.