3. Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.
4. Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
5. Nitoriti ẹnyin ti mu fàdakà mi ati wurà mi, ẹnyin si ti mu ohun rere daradara mi lọ sinu tempili nyin:
6. Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn.
7. Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin.