Jer 41:15-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ṣugbọn Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, bọ́ lọwọ Johanani pẹlu ọkunrin mẹjọ, o si lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.

16. Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, si mu gbogbo iyokù awọn enia ti o ti gbà lọwọ Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati Mispa, lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ani, akọni ọkunrin ogun, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn iwẹfa, awọn ti o ti tun mu pada lati Gibeoni wá:

17. Nwọn si kuro nibẹ, nwọn si joko ni ibugbe Kinhamu, ti o wà lẹba Betlehemu, lati lọ ide Egipti.

18. Nitoriti ẹ̀ru ba wọn niwaju awọn ara Kaldea, nitoriti Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ẹniti ọba Babeli fi jẹ bãlẹ ni ilẹ na.

Jer 41