Jer 40:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà.

11. Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn;

12. Gbogbo awọn ara Juda si pada lati ibi gbogbo wá ni ibi ti a ti lé wọn si, nwọn si wá si ilẹ Juda sọdọ Gedaliah si Mispa, nwọn si kó ọti-waini ati eso igi jọ pupọpupọ.

13. Ṣugbọn Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà li oko, tọ̀ Gedaliah wá si Mispa.

14. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ dajudaju pe: Baalisi, ọba awọn ọmọ Ammoni, ti ran Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati pa ọ? Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, kò gbà wọn gbọ́.

Jer 40