16. Pe, Bayi li Oluwa wi niti ọba ti o joko lori itẹ́ Dafidi, ati niti gbogbo enia, ti ngbe ilu yi, ani niti awọn arakunrin nyin ti kò jade lọ pẹlu nyin sinu igbekun.
17. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o rán idà sarin wọn, ìyan, ati àjakalẹ-àrun, emi o ṣe wọn bi eso-ọ̀pọtọ buburu, ti a kò le jẹ, nitori nwọn buru.
18. Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si.
19. Nitoriti nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ mi, li Oluwa wi, ti emi rán si wọn nipa awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, emi dide ni kutukutu mo si rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ igbọ́, li Oluwa wi.