Jer 19:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nwọn ti kọ́ ibi giga fun Baali pẹlu, lati fi iná sun ọmọkunrin wọn, bi ẹbọ-ọrẹ sisun fun Baali, eyiti emi kò pa laṣẹ lati ṣe, ti emi kò si sọ, tabi ti kò si ru soke ninu mi:

6. Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa.

7. Emi o sọ igbimọ Juda ati Jerusalemu di asan ni ibi yi; emi o mu ki nwọn ki o ṣubu niwaju ọta wọn, ati lọwọ awọn ti o nwá ẹmi wọn, okú wọn ni a o fi fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko ilẹ fun onjẹ.

8. Emi o si sọ ilu yi di ahoro, ati ẹ̀gan, ẹnikẹni ti o ba nkọja lọ nibẹ yio dãmu, yio si poṣe nitori gbogbo ìna rẹ̀.

9. Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ.

10. Nigbana ni iwọ o fọ igo na li oju awọn ti o ba ọ lọ.

Jer 19