1. LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili.
2. Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò.
3. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀.
4. Awọn òpo ilẹ̀kun si mì nipa ohùn ẹniti o ke, ile na si kún fun ẹ̃fin.