1. KE rara, máṣe dasi, gbe ohùn rẹ soke bi ipè, ki o si fi irekọja awọn enia mi hàn wọn, ati ile Jakobu, ẹ̀ṣẹ wọn.
2. Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun.