Isa 57:8-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Lẹhin ilẹkùn ati opó ilẹkun ni iwọ si ti gbe iranti rẹ soke: nitori iwọ ti fi ara rẹ hàn fun ẹlomiran dipò mi, iwọ si ti goke: iwọ ti sọ akete rẹ di nla, iwọ si ba wọn dá majẹmu; iwọ ti fẹ akete wọn nibiti iwọ ri i.

9. Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú.

10. Ãrẹ̀ mu ọ ninu jijìn ọ̀na rẹ: iwọ kò wipe, Ireti kò si: ìye ọwọ́ rẹ ni iwọ ti ri; nitorina ni inu rẹ kò ṣe bajẹ.

Isa 57