18. Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.
19. Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ.
20. Yio si ṣe li ọjọ na, ni emi o pè Eliakimu iranṣẹ mi ọmọ Hilkiah.
21. Emi o si fi aṣọ-igunwà rẹ wọ̀ ọ, emi o si fi àmure rẹ dì i, emi o si fi ijọba rẹ le e li ọwọ́: on o si jẹ baba fun awọn olugbé Jerusalemu, ati fun ile Juda.