2. Tes 2:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro.

8. Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan:

9. Ani on, ẹniti wíwa rẹ̀ yio ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke,

10. Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.

11. Ati nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ́:

12. Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo.

2. Tes 2