1. EYI li o di igba kẹta ti emi ntọ̀ nyin wá. Li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta li a o fi idi ọ̀rọ gbogbo mulẹ.
2. Mo ti sọ fun nyin ṣaju, mo si nsọ fun nyin tẹlẹ, bi ẹnipe mo wà pẹlu nyin nigba keji, ati bi emi kò ti si lọdọ nyin nisisiyi, mo kọwe si awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ati si gbogbo awọn ẹlomiran, pe bi mo ba tún pada wá, emi kì yio da wọn si:
3. Niwọnbi ẹnyin ti nwá àmi Kristi ti nsọ̀rọ ninu mi, ẹniti ki iṣe ailera si nyin, ṣugbọn ti o jẹ agbara ninu nyin.