24. Ṣugbọn ẹnyin ni mo nsọ fun, ẹnyin iyokù ti mbẹ ni Tiatira, gbogbo ẹnyin ti kò ni ẹkọ́ yi, ti kò mọ̀ ohun ijinlẹ Satani (bi nwọn ti nwi), emi kò dì ẹrù miran rù nyin.
25. Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de.
26. Ẹniti o ba si ṣẹgun, ati ẹniti o ba pa iṣẹ mi mọ́ titi de opin, emi o fun u li aṣẹ lori awọn orilẹ-ède:
27. On o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn; bi ã ti ifọ́ ohun elo amọ̀koko li a o fọ́ wọn tũtu: bi emi pẹlu ti gba lati ọdọ Baba mi.
28. Emi o si fi irawọ owurọ̀ fun u.
29. Ẹniti o ba li eti, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmi nsọ fun awọn ijọ.