4. Wọnyi ni igi oróro meji nì, ati ọpá fitila meji nì, ti nduro niwaju Oluwa aiye.
5. Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a.
6. Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ.
7. Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn.