4. Nigbana li o jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, o si ṣe atipo ni Harani: lẹhin igbati baba rẹ̀ kú, Ọlọrun mu u ṣipo pada wá si ilẹ yi, nibiti ẹnyin ngbé nisisiyi.
5. Kò si fun u ni ini kan, ani to bi ẹsẹ ilẹ kan; ṣugbọn o leri pe, on ó fi i fun u ni ilẹ-nini, ati fun awọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati kò ti ili ọmọ.
6. Ọlọrun si sọ bayi pe, irú-ọmọ rẹ̀ yio ṣe atipo ni ilẹ àjeji; nwọn ó si sọ wọn di ẹru, nwọn o si pọ́n wọn loju ni irinwo ọdún.
7. Ọlọrun wipe, Orilẹ-ède na ti nwọn o ṣe ẹrú fun, li emi ó da lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade kuro, nwọn o si wá sìn mi nihinyi.
8. O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila.