Iṣe Apo 23:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ.

22. Nigbana li olori ogun jọwọ ọmọkunrin na lọwọ lọ, o si kìlọ fun u pe, Máṣe wi fun ẹnikan pe, iwọ fi nkan wọnyi hàn mi.

23. O si pè meji awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ mura igba ọmọ-ogun silẹ, lati lọ si Kesarea, ati adọrin ẹlẹṣin, ati igba ọlọkọ̀, ni wakati kẹta oru;

24. O si wipe, ki nwọn pèse ẹranko, ki nwọn gbé Paulu gùn u, ki nwọn si le mu u de ọdọ Feliksi bãlẹ li alafia.

25. O si kọ iwe kan bayi pe:

26. Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.

27. Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe.

28. Nigbati mo si nfẹ mọ̀ idi ọ̀ran ti nwọn fi i sùn si, mo mu u sọkalẹ lọ si ajọ igbimọ wọn:

29. Ẹniti mo ri pe, nwọn fisùn nitori ọ̀ran ofin wọn, bẹ̃ni kò dà ọ̀ran kan ti o tọ́ si ikú ati si ìde.

Iṣe Apo 23