31. Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú.
32. Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu.
33. Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe.
34. Awọn kan nkígbe ohun kan, awọn miran nkigbe ohun miran ninu awujọ: nigbati kò si le mọ̀ eredi irukerudò na dajudaju, o paṣẹ ki nwọn ki o mu u lọ sinu ile-olodi.
35. Nigbati o si de ori atẹgùn, gbigbé li a gbé e soke lọwọ awọn ọmọ-ogun nitori iwa-ipa awọn enia.
36. Nitori ọ̀pọ enia gbátì i, nwọn nkigbe pe, Mu u kuro.
37. Bi nwọn si ti fẹrẹ imu Paulu wọ̀ inu ile-olodi lọ, o wi fun olori-ogun pe, Emi ha gbọdọ ba ọ sọ̀rọ? O si dahùn wipe, Iwọ mọ̀ ède Hellene ifọ̀?
38. Iwọ ha kọ́ ni ara Egipti nì, ti o ṣọ̀tẹ ṣaju ọjọ wọnyi, ti o si ti mu ẹgbaji ọkunrin ninu awọn ti iṣe apania lẹhin lọ si iju?