33. Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni.
34. Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi.
35. Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ.
36. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura.