4. Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò.
5. Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri:
6. Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.
7. Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ: