32. Iwọ o ri wahala ti Agọ, ninu gbogbo ọlà ti Ọlọrun yio fi fun Israeli: kì yio si si arugbo kan ninu ile rẹ lailai.
33. Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn.
34. Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú.
35. Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo.