1. NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò.
2. O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀.