3. Emi mọ̀ Efraimu, Israeli kò si pamọ́ fun mi: nitori nisisiyi, Efraimu, iwọ ṣe agbère, Israeli si dibajẹ.
4. Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa.
5. A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn.
6. Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn.