5. Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.
6. Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
7. Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara.
8. Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi.
9. Ati emi, Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ̀ Egipti wá, yio si tún mu ọ gbe inu agọ, bi ọjọ ajọ-ọ̀wọ wọnni.
10. Emi ti sọ̀rọ nipa awọn woli pẹlu, mo si ti mu iran di pupọ̀, mo ti ṣe ọ̀pọlọpọ akàwe, nipa ọwọ́ awọn woli.