7. O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ.
8. O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ;
9. Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀.
10. O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ.
11. Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ.