Gẹn 8:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ.

11. Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ.

12. O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́.

13. O si ṣe li ọdún kọkanlelẹgbẹta, li oṣù kini, li ọjọ́ kini oṣù na, on li omi gbẹ kuro lori ilẹ: Noa si ṣí ideri ọkọ̀, o si wò, si kiyesi i ori ilẹ gbẹ.

14. Li oṣù keji, ni ijọ́ kẹtadilọgbọ̀n oṣù, on ni ilẹ gbẹ.

15. Ọlọrun si sọ fun Noa pe,

16. Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ.

17. Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ.

Gẹn 8