Gẹn 42:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju?

2. O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú.

3. Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti.

Gẹn 42