Gẹn 31:53-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

53. Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura.

54. Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na.

55. Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.

Gẹn 31