Gẹn 26:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa.

11. Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.

12. Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:

13. Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi.

14. Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀.

Gẹn 26