Gẹn 16:4-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. On si wọle tọ̀ Hagari, o si loyun: nigbati o ri pe on loyun, oluwa rẹ̀ obinrin wa di ẹ̀gan li oju rẹ̀.

5. Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ.

6. Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀.

Gẹn 16