Gẹn 14:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke.

11. Nwọn si kó gbogbo ẹrù Sodomu on Gomorra ati gbogbo onjẹ wọn, nwọn si ba ti wọn lọ.

12. Nwọn si mu Loti, ọmọ arakunrin Abramu, ti ngbé Sodomu, nwọn si kó ẹrù rẹ̀, nwọn si lọ.

13. Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀.

Gẹn 14