18. Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe?
19. Ẽṣe ti iwọ fi wipe, arabinrin mi ni iṣe? bẹ̃li emi iba fẹ ẹ li aya mi si: njẹ nisisiyi wò aya rẹ, mu u, ki o si ma ba tirẹ lọ.
20. Farao si paṣẹ fun awọn ọkunrin rẹ̀ nitori Abramu: nwọn si sìn i jade lọ, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni.