Gẹn 10:20-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn.

21. Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ.

22. Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.

23. Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi.

24. Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi.

25. Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.

26. Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,

27. Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,

Gẹn 10