Esr 2:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Awọn ọmọ Adini, adọtalenirinwo o le mẹrin.

16. Awọn ọmọ Ateri ti Hesekiah, mejidilọgọrun.

17. Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹta.

18. Awọn ọmọ Jora, mejilelãdọfa.

19. Awọn ọmọ Haṣumu igba o le mẹtalelogun.

20. Awọn ọmọ Gibbari, marundilọgọrun.

21. Awọn ọmọ Betlehemu, mẹtalelọgọfa.

22. Awọn enia Netofa, mẹrindilọgọta.

23. Awọn enia Anatotu, mejidilãdọje.

Esr 2