Eks 3:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun.

2. Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run.

3. Mose si wipe, Njẹ emi o yipada si apakan, emi o si wò iran nla yi, ẽṣe ti igbẹ́ yi kò run.

Eks 3